Stella Dimoko Korkus.com: ORIKI NI ILE YORUBA

Advertisement

Advertisement - Mobile In-Article

Wednesday, 8 November 2017

ORIKI NI ILE YORUBA

Kilo shele?Ema bo,je ka ko yoruba....Emi ni Stella.mon ko intro...Hahahahahahahahahahahhaha

Oriki je asa kan ti o je iran Yoruba l’ogun pupo, eyi si mu won yato si awon iran yoku patapata, ko si ojulowo omo kaaro- o- o- jiire , ti ko ni oriki, yala oriki orile ni tabi oriki idile ati paapaa oriki oruko.Oriki je awon oro isiri ti awon Yoruba maa n fi yin ara won tabi eni ti inu won ba dun si.


Orisirisi iran ti won maa n ki ojulowo omo Yoruba mo niwonyi; iran Alaran, Aagberi, Olu-oje, Osulakesan, Ijamogbo, Onikoyi, Oko irese, Ajisola, Ologbin-in, Opomulero, Olofa, Olokun-Esin, Olufe, Elerin, Ijese, Iloko, Orin, Aresa.
Oriki orile ni ewi alohun ti o n so nipa itan awon baba nla eni ni ile Yoruba, idile ti won ti se wa,orirun iran, ise akin ti won ti gbe ile aye se, ise iran naa ati beebee lo.


Oriki idile a maa so nipa irisi iran, isesi, eewo iran, ise iran, aleebu iran ati beebee lo.


Oruko oriki ni oruko keji ti awon Yoruba maa n fun omo ni ojo isomoloruko yala okunrin tabi obinrin bi apeere;
Ajoke, Amope, Isola, Atoke, Ajao, Arike, Abike, Ajani .Aimoye awon omo wa in won ko ni oruko oriki mo ti kosi daara.


Daruko orike re .


Bv Olori Orente

60 comments:

Olori Orente said...

Hahahaha
Stella funrare,obirin bi okunrin
Oriki WO in ka fun Stella ooo

Chike TEFLON said...

Ek'aro.

Emi Omo Igbo.

Mi o bo..

Olori Orente ewa explain.

Pastor Sexy Daddy said...

Bawaoni?

Shotigbo?

Olaniyi

Yemisi..Lol

Mrs A said...

Hahahaha deola 9c one o

Oriki yi mu mi ranti iya iya mi (olorun a tun bo ma bami te si afefe we)

Queen_Bee said...

Amoke

Emmy said...

E ku ise opolo,e ku aigbagbe. Arinke l'oriki t'emi o. A de maa nki idile wa ni Omo"Olufe". E ku ise takuntakun o. Oodua a gbe wa o😁

SOMETHING-LIGHT said...

I no fit cum give mysef headache.


Bounce out of post👟👟👟👟👟

Olori Orente said...

Arike ni oriki Stella Lati eni lo

Olori Orente said...

Chike bawoni
Ti oba ti ma komi ni IGBO,ma ko e ni yoruba

Olori Orente said...

Pastor showapa
Kini oriki ee

Olori Orente said...

Emi na ranti iya baba mi ni oooo
Orun re, OMA kimi titi,
Abike

Olori Orente said...

Abike

Olori Orente said...

Amin oooo
Ekasan ooo

TheLagosShopper(Goods and services 4rm the popular Lagos markets to anywhere in naija?07030493148) said...

Asake ni oriki mi,oun sini olowo-orimi man pee mi......hahahaha!!

Anonymous said...

Amope Okin Omo Olofa mojo.

Omo abisu joruko, ijakadi loro ofa.
Omo ijakan ti won jaa l'Ofa lojosi.
Molose oju kini? Ose oju poro loko, osoju agbele yaraara. Iba soju Oloko Iba lawon. Omo buu re, laare, okan ogbodo jookan. Tori bokan ba jokan lo no ile Olalomi, ogun nii kowan roro. My Town (Offa, Kwara State) has got to have the most popular Oriki of them all.
#UmmuKam

Chike TEFLON said...

Olori Orente, mi ofe eleyi ooo.
Kini gbogbo eleyi?
Ewa clear me, you carry more confusion gimme.
😂😂😂😂

Chike TEFLON said...

Emi da da
Before I forget.

Chameleon said...

oriki baba mi ni ogogo òmò kulodo. mi o mó oriki temi sugbon olomi ni òkò mi maa n pemi.

jhoke is a bae said...

Arike ni oriki to e mi Na ...emi omo opomulero mojalekan opo roso opo panja

Queen Lizzy said...

Arike ni oriki mi, Olori Orente o ko so oriki re funwa o... Bawo ni gbogbo nkan, se ise nlo deede... O gbiyanju fun eyi ti o se yi o.. Gba ikonu (kisses) ife..

MrsB said...

Abike [Ìyá mi]
Ajoke [èmi]
Atoke [Omo mi]

Omeh said...

Eku ise OLUWA o.

Anonymous said...

Emi ni Adunni, omo Arulogun bi eefi; omo o'shoro da egberun eshinshin bora; omo oko isu si aja ki aja ro giirigi, omo ara oko ko gbodo she bi ara ile!!!


Arulogun fihan wipe jagunjagun ni awon iran Baba to bi mi l'omo


Osh'oro da egberin ashinshin bo'ra- ni ojo pipe, Ogun ni won bo ni idile wa, bi won ba ti be ori aja si Ogun tan, eni ti o be a ro eje ori aja naa si ori ara re ki o to fi ori aja naa si'di Ogun. Eshinshin a maa kun onitohun nitori eje aja yi, ti o fa oriki "osho'ro da egberun eshinshin bora"


"Oko isu si aja ki aja ro giiriri"- Nigba ti ko ba si ogun, awon Baba Baba mi a ma shishe agbe, won si je akikanju ni idi she yi, isu won maan ta daada, idi ti won fi n ki wa bee niyi.


Toor, labare lara oriki ara mi ati idile niyi, owo n ro mi, mo fe sinmi.


Bi a ba ri eni ti o le ka, ti otun le tunmo ohun ti mo ko si ede geesi to dangajia, mo pinu egberun mewa naira fun eni bee.


Nitooto, ede Yoruba dun!

SHARONNA

Anu Funke said...

O ku òpòló..... oriki mi ni Asábì. Iya mi lo funmi ni oriki yii nitori wipe Asabì ni oruko iya won.
Tì olowo orì mi bati se mi,ti o si fe bèbè ti o ba ti kìì mi daada pelu oriki mi, orimi asi maa wu bi gaari ifò😁😁...Ija ti pari niyen.

Taiwo Oluwatosin said...

Emi omoyeleru,omo asowola gbendeke, omo olobo NLA isiwo tofiberu to fi bimo tofibi olori lafin Oba. Omo Petu ado, omo aimarasa Omo lukere ogboye gbokogbaila.

Taiwo Oluwatosin said...

Emi omoyeleru,omo asowola gbendeke, omo olobo NLA isiwo tofiberu to fi bimo tofibi olori lafin Oba. Omo Petu ado, omo aimarasa Omo lukere ogboye gbokogbaila.

Cisca Chesca said...

Shey dada le wan?
Awon omo nkan o

Odabo o😂😂😂

Anonymous said...

Ayinke no oriki ti e mi. Omo Ede ni iya mi. Awon ni won ma n ki wipe "Opomulero moja alekan omo esu. Opo ro so. Opo gba ja.Baba mi je omo ilu Eko, Awon ni won ma ki ni "Eko aro mi sa legbelegbe.Mo so tun fe omo Ibadan, Ibadan ni ile oluyole,nibi Ole gbe n jare olohun. Olori Orente e ku ise opolo, a ma ju yin se o.Amin

Anonymous said...

A won okunrin mo yi oriki yii gidigan ni, oko mi a ma SAA mi to ba fe GBA nkan lowo mi.

olami4eva said...

Emi Abebi
Omo olokun seri ade
Omo arije sopo ile
Omo olokun ajifiluki
Omo olokun aji fi eran nla bo
Omo olokun agana erin
Erin beji oyaso
....
#mumisaac

Olori Orente said...

Lol......Chike biko fimile ooo

Olori Orente said...

Asake oriki iya baba mi

Olori Orente said...

Oriki yi dun gan ooo

Olori Orente said...

Omo Ilaro abi ota ni yin ni?

BettyO said...

Bawo ni
Ema bi nu
E' Pele

Hope my Yoruba is on point @ olori orente.

Olori Orente said...

Omo iya mi
Abike ni oriki temi
Adupe ooo,ao se are

Ikonu Ife temi naa

Olori Orente said...

Abike lemi
Arike Aburo mi
Alamu Aburo mi

Cynthia Iyede said...

E mi o ki'n se omo yoba amo mogbo yoba di e.

Oko mi ma npe mi ni morenikeji, eni keji mi, eni ti okan mi fe.

Olori Orente gbayi!

Olori Orente said...

Adunni oriki re dun gan ooo
Aku igbe ede wa laruge

sylvia said...

What does Ajike mean pls?

Kendrick's mum said...

Olori omo'dada!

Omo'to fine!

Ekun'gbadun!

Eka'ro

Ese'un oh

Alafia alafia

Oda'bo

Olori Orente said...

Kendrick mooma toh dun
Ekasan ooo

The Grey Goose said...

@ Arabirin Sharonna, itumo yoruba ti e ko ni ede geesi lo bayii." I am Adunni,the child of the one that is fierce in battle like smoke. The child of Osh'oro who is covered with a thousand flies. The child of one who keeps yams in the barn till it becomes mighty. The child of one who is an indigene that must not behave like an outsider. Arulogun means that my father's ancestors were mighty warriors Osh'oro who is covered by a thousand flies. A long time ago, my family were "Ogun" worshippers, During the festival of Ogun worship, the person that cuts off the head of the dog used in the worship will pour the blood coming out of the head of the dog on his own head before dropping the head of the dog at the shrine of Ogun,The head cutter becomes covered with flies due to the blood he has poured on his head hence the praise Osh'oro coverd in a thousand flies. The one who puts yam in the barn till it becomes mighty. When there is no war, my forefathers are farmers and they are hard working when it comes to farming so they do have a bountiful harvest.Because they harvest big yams hence the praise of having a mighty barn.
Translation by The Girl

Olori Orente said...

Awwwe iyen na dun oooo
Cynthia monife bi ESE gbo Yoruba yen

Olori Orente said...

Obinrin toh rewa
Egbiyanju gan
Eku ise

Olori Orente said...

Eleyi wun mi ooo
Isaac nko

Olori Orente said...

Amin oooo ati eyin na ooo

Olori Orente said...

Adupe ooo
Awa ni alafia ooo

Olori Orente said...

Eku use omo odo agba

Olori Orente said...

Bi oko mi na shey ma n mu Simi Lori niyen

Babalola Zumrat said...

Nle Oooooo Omo Alagbe Nwa Jegbin Jora.Jegbin Jora Kole Joye Pe Ni Won Ki Iba Aron Mu Onshile Iba Aran Mama Dahun.Iba Alaka Loko Iba Gbedudu Maro, Ole Kati Odo Ojojo. Ojojo Iba Shole Kon ton Logun Odun Niwon Ki Ba Aronmu Ohunshile. Oriki Idile Baba Mi Re Ni ILE-OGBO NI OSUN OSHOGBO.Opo Ju Bayi Lo Mo Ko Ni Ki Fun Yin Ni Tansho Ni Nu E Ni.

Kendrick's mum said...

Ose omo'aiye!

Enu kami oooo!

Wa gba yi joor!

deenity Sealord said...

Hmmmm I Tuale u @ the grey goose..gbayiii

deenity Sealord said...

Emi ni iloti, Omo agbo, Omo oloti subu, Omo oloti ape, Omo oloti to subu mati di de

Uberhaute| +234 8151914305|Beauty Therapy| Sales n Services said...

Opómúléró mo jaàlekàn
Òpó róso, òpó bàjá
Omo Oníkòyí,
Ìkòyí èsó ni pelemo,
Lójú Ogun.

Uberhaute| +234 8151914305|Beauty Therapy| Sales n Services said...

Ìdílé ìyá

Ìsàgá òkunmàsè
Ahéré owó ò ní gbàgede
Omo abéré méta,
Òkán se, òkán nù.
Òkan yóku la fi n rángba aso
Omo Oba Séru.

I've always been warned never to tell people my oríkì name anyhow because of spiritual connotations.

Olorì Òrenté, e kú isé opolo.

Anonymous said...

I

ife4ril said...

Let me try to interprete...oshoro da egberin esinsin bora...long ago your forefathers were warriors and they worshipped Ogun...when sacrificing to Ogun, (dogs were used) the executioner or beheaded will behead the dog and pour the dog's blood on his own head, after which he will lay the dog's head at Ogun's shrine. Due to the blood on his head, houseflies will be attracted to it hence the accolade...he covers himself with a thousand flies.
Oko isu so aja, ki aja to giiriri...this means that in the absence of war or at the time of peace, your ancestral fathers will take up farming. They were so hardworking and dedicated that the products (mainly yam) were robust and fruitful. This birthed the title.
Omo oko ko gbodo se bi ara ile...loosely this means that the villager must not behave like the townsmen. This means that one should be true to who he is and not pretend to be someone else. Originality is important
Looto ede Yoruba fun poo
Hope my 'geesi' was 'dangajia' enough?
Yours truly
Toyobaby

Anonymous said...

Emi ni Abike, Omo Ikoyi Eso...

Dame sexy said...

Olori Orente e ku ise opolo oh!
Oriki mi ni Awero okin, emi ni omo Ibadan n' le Oluyole,
nibi ole gbe n jare olohun.Maja maja ni ti Ibadan to fi ko ara iwaju leru.
Ibadan ilu t'Ojo, ilu T'aJADI, ilu OGUNMOLA .
Asabi, Asake ati Apeke ni oriki awon omo mi.
Oke Ibadan a gbe wa lagbara eje Jesu kiristi.AMIN.
MO gbe osuba nla fun @ the grey goose and @ife4ril!
e ku ise opolo fun itumo geesi ti e se fun oriki yen.

Related Posts Plugin for WordPress, Blogger...

Advertisement