Stella Dimoko Korkus.com: Asa Igbeyawo Ati Oju Ise Alarina Laye Atijo

Advertisement

Advertisement - Mobile In-Article

Wednesday, August 22, 2018

Asa Igbeyawo Ati Oju Ise Alarina Laye Atijo

O je ohun Pataki fun okunrin tabi obinrin lati se igbeyawo ni igba atijo. Ni igba ti a ba gbadura fun eniyan ni ile yoruba,
igbeyawo wa lara re.




Gbogbo eto lesese la ma menu baa.


1.IFOJUSODE



Nigba ti odomokunrin kan ba ti balaga, awon obi re yoo ti bere si fi oju sile boya nwon a le ri omobinrin kan tin won yoo fe fun omo won.Omokunrin yi paapaa laije pe enikeni so fun un,yoo bere si se finnifinni ju ti ateyinwa lo; yoo we nigba meta loojo, yoo toju eyin, enu,eekanna owo ati tese, gbogbo ara yoo si maa jolo. Ni kete ti okunrin ba fi oju kan wundia
(omobinrin ti ko ti mokunrin) ti o je oju ni
gbese, ise wa di ti alarina.



2.ALARINA



Alarina ni eni ti o ngbokegbodo laarin
omokunrin ati omobinrin ti wo ba ni ife si ara won. Awon obinrin lo saba maa nsise yi daradara. Ise alarina ni lati wa idi ohun gbogbo kinnikinni nipa omobinrin yi. Idi re ti a fi nwa idi ni wipe ko si eni ti yoo fe gbe eni ti won n dete ni idile won, tabi iran asinwin, tabi obinrin onijagidijagan ni iyawo. Ise alarina ni lati pon ati latI ge omokunrin yi loju omobinrin ki o si la oju agi si agi (yoo seto bi omokunrin
yoo se pade omobinrin).



3.ISIHUN TABI IJOHEN


Leyin igba ti alarina ba ti la oju awon mejeeji kan ara won, omokunrin ati omobinrin yi yoo bere si pade ni orisirisi ibi (labe igi odan nigba osupa, ni eyin ilea won omobinrin). Leyi igba ti won ba ti se eleyi fun igba pipe, omobinrin yoo wa je hoo fun lati gba beni yoo sofun omokunrin ki o seto bi baba ati iya oun yoo se gbo nipa ore won. Gbigba ti omobinrin gba yi ni awa Yoruba npe ni Ijohen tabi Isihun .




4.ITORO



Leyin igba ti omobinrin ba ti juwo sile patapata, omokunrin yoo lo so fun baba re pe oun ti ri ododo kan ti o pupa, ti o si lewa ni ile Lagbaja tabi Lakasogbe ti oun fe ja. Baba re yoo wa bi lere boya ododo naa yoo see ja tabi ko ni see ja.


Omokunrin naa yoo wa so gbogbo adehun ti oun ati omobinri yi ti se fun ara won. Eyi ni yoo fun baba re ni anfani lati lo baa won agbaagba adugbo re soro gegebi won yo se lo toro omo.
Ni igba kini tin won yoo lo ri baba omobinrin,baba omokunrin ati omo ile kan tabi meji ni yoo lo. Owuro kutu hai ni nwon si maa nrin iru irin yi. Nwon o ko, nwon yoo soro fun baba omobinrin. Oro yi ko ni je kayefi si baba omobinrin yi notori o ti bere si ri irin ese omo re. Idahun ti baba yi yoo si fun awon wonyi nipe kii se oun nikan lo bimo yi ati pe kin won wa pade molebi oun ni ojo bayibayi.




5.IDANA



Leyin igba ti won ba ti toro omo tan,idana ni gbogbo won yoo fi okan si. Gbogbo awon ti o ye kin won gbo nipa itoro ti nwon ko gbo, ati gbogbo awon ti o gbo ti won ko ri aye lo, akoko niyi lati fi owo si. Awon idile mejeeji yoo ranse si awon eniyan won nibikibi ti nwon ba wa.
Idana yi se Pataki pupo nitori ibe ni awon idile mejeeji ti maa npade lekunrere. Ni ojo idana yi awon iyawo baba omobinrin ati iyawo baba omokunrin yoo pagbo ere, olukuluku won yoo maa ki oko won. Owuro kutukutu tabi irole patapata ni a nse idana. Lati ile omokunrin ni nwon ti maa ru gbogbo ohun idana wa.




6.AWON OHUN IDANA



Oyin, ireke ati iyo – eyi nip e aye won a dun;obi ati orogbo- eyi nip e nwon yoo gbo (dagba),atare- eyi nip e iyawo yoo bimo pupo; epo- eyi ni wipe yoo de won lara. Leyin eyi ni nwon yoo waru opolopo emu ati opolopo oti oyinbo fun mimu awon ti o wa sibi aseye naa. Gege bi asa
Yoruba, eni ti o dagba ju nile iyawo yi ni yoo fa iyawo le eni ti o dagba ju ni ile oko lowo. Yoo sika awon iba die funn alagba yipe nwon kii na omo won; ebi kii pa, kii je gbaguda (ege) ati beebee lo.




7.IPALEMO



Eyi tio ku ni ki iyawo maa pa ile re mo diedie leyin ti won ti dana tan. Ona meji ni oko iyawo le gba lati ran iyawo re lowo lati palemo.


Ona kini, oko iyawo le fun iyawo re ni owo lati pese aso ati yeti ti yoo maa lo ni ile oko. Ona keji ni ki oko be eniyan fun ara re lati ra gbogbo awon nkan wonyi, ki o si lo gbe e fun iyawo re lodidi.



8.IGBEYAWO


Igbeyawo ma nyato lati agbegbe si agbegbe; lati ilu kan si ilu keji ati lati ileto si ileto. Sugbon,awon nkankan wa ti o je pe ko le yato niwon igba ti o ba ti je ile Yoruba ni a ti n se igbeyawo naa. Ni oju ale patapata ni iyawo maa nlo si ile
oko re. Ni ojo igbeyawo yi, ati ile iyawo ati ile oko, ojo ti o yato ninu ojo nii se.


Nigba ti iyawo ba fe kuro ni ile awon obi re,gbogbo awon obi re ati awon ibatan obi re ni yoo pejo. Olori idile won ni yoo si saaju lati gbadura fun iyawo naa pelu omije loju, iyawo naa yoo maa se amin pelu omije, gbogbo ile a si maa gbadura fun omidan yi leselese pelu omije.
Yoruba ma n pe ekun ti awon to n gbadura funiyawo n sun ni isun idagbre ti won si ma n pe ekun ti iyawo nsun ni ekun iyawo.


Nigba ti iyawo ba ti nsunmo ile oko re, oko re gbodo jade ni ile nitori eewo ni ni ile Yoruba ki iyawo ba oko re ni ile. O je asa ni awon agbegbe kan lati pa ohun eleje si ese iyawo ki o to wo ile oko re. Sugbon ki iyawo to wo ile oko re ni awon agbegbe miran, a gbodo fi omi we ese re ni enu ona. Nigba ti iyawo ba wole gbara, odo olori idile ni nwon yoo muu lo. Ibe
ni a o ti sure fun un.


Asa Yoruba ni ki oko sunmo iyawo re ni ale ojo keta lati mo boya o ti mo okunrin kan tele tabi ko mo okunrin rara. Ti iyawo ba ti mo okunrin,
oro itiju patapata ni fun ohun ati molebi re, paapaa julo iya re. Sugbon bi iyawo ko ba ti mo okunrin kan tele, gbara ti oko iyawo ti se tan ni ariwo yoo ti so ni ile won. Awon ara ile won yoo si ko ere lo si ile baba iyawo ti won yoo si maa sajoyo pe awon ba omo won nile.





This post simply talks about Marriage rites in the Olden days.........

19 comments:

  1. Eto igbeyawo laye, oba Oluwa lo fi le le pelu ase ni.

    ReplyDelete
  2. Ekaro, Ekasan Nile ooo
    Emabinu pe o gun gan
    Moki gbogbo awon musulumi ododo,ku odun
    Emi yi o shey opolopo

    Oya eje ka fi oro jomi toro oro

    ReplyDelete
  3. Loans available for salary earners in Abuja contact me on 0802695863822 August 2018 at 12:26

    Olorun afi ibukun si gbogbo igbeyawo

    ReplyDelete
  4. Kam biakwanu.( I dey come) @Princess Tever

    ReplyDelete
  5. That chair is all I see.. LMAO πŸ˜πŸ˜€πŸ˜πŸ˜€πŸƒπŸƒπŸƒπŸƒπŸƒπŸƒ

    ReplyDelete
  6. Eto igbeyawo a maa dun ni aye atijo. Gbogbo yamayama ti mo n ka nipa kosiini (cousin) ti wo n fe ara won ko le shele lai lai.
    Orisirisi anfaani ni o wa nine. Sugbon, olaju ti ba aye je, civilization ti pa pupo ninu asa wa.

    Olori Orente, e ku ise takuntakun. Ire o!!!!

    ReplyDelete
    Replies
    1. Oro kosini yen o ma nisosi
      Omo iya😘😘😘😘😘

      Delete
  7. olori Ku ise opolo, sugbon apoti iyanu Yi ga gan o

    ReplyDelete
  8. Eku ise opolo o. Eto igbeyawo ni aye atijo je oun to awon eniyan ponle gidigan,ko da bi aye ode oni ti won ti so o di idakuda.

    ReplyDelete
  9. Omo this one gidigan, igeyawo je ohun nla ni ile yoruba, I pray goodness and favour into every marriages IJN

    ReplyDelete
  10. Olori Orente, eni iyi, eni eye. E ku ise opolo oh. Ibeere temi ni wipe, Se ni ile Yoruba nikan ni a ti n se akiyesi awon asa igbeyawo yi ni abi ni ile gbogbo eleya dudu ni? ati wipe kini ibale obirin niise pelu ibagbe ati ibalopo pelu oko re leyin igbeyawo laye atijo?

    ReplyDelete
    Replies
    1. Omo iya, ile yoruba ni atin shey igbeyawo eleyi
      Nitori Yoruba MA n Gbe asa igbeyawo laruge

      Nipa ibale iyawo, iya MI fi yemi wipe obinrin ti won ko baba nile laye igbayen koni iyi rara.

      Sugbon olaju tiyi nkan pada.

      Delete

Disclaimer: Comments And Opinions On Any Part Of This Website Are Opinions Of The Blog Commenters Or Anonymous Persons And They Do Not Represent The Opinion Of StellaDimokoKorkus.com

Pictures and culled stories posted on this site are given credit and if a story is yours but credited to the wrong source,Please contact Stelladimokokorkus.com and corrections will be made..

If you have a complaint or a story,Please Contact StellaDimokoKorkus.com Via

Sdimokokorkus@gmail.com
Mobile Phone +4915210724141