Stella Dimoko Korkus.com: Aseju Baba Asete.......

Advertisement

Advertisement - Mobile In-Article

Wednesday, October 25, 2017

Aseju Baba Asete.......

Ejoor,se egbo yoruba ni?

Ni ìgbà àtijọ́, ọkùnrin kan wa ti orúkọ rẹ njẹ́ Ìgbéraga. Wọ́n bi Ìgbéraga si ilé olórogún, àwọn ìyàwó bàbá́ rẹ yoku ni ó tọ nitori ìyá rẹ kú nigbati ó wà ni kékeré. Lẹhin ti o tiraka lati pari iwé mẹ́fà, gẹ́gẹ́ bi ọ̀dọ́, ó gbéra lọ si ilú Èkó nibiti ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ Ẹlẹ́ja.


Ó nṣe dáradára ni ibi iṣẹ́ ki ó tó gbọ́ ìròyìn ikú bàbá rẹ. Ìgbéraga pinu lati padà si ilú rẹ lati gba ogún ti ó tọ́ si lára oko kòkó rẹpẹtẹ ti bàbá rẹ fi silẹ̀. Ohun fúnra rẹ ra oko kún oko bàbá rẹ ti wọn pín fun. Ó di ẹni ti ó ri ṣe ju àwọn ọmọ bàbá rẹ yoku. Eyi jẹ ki gbogbo àwọn ọbàkan rẹ gbójú le fún ìrànlọ́wọ́.


Ni igbà ti ó yá, o ni ilé àti ọlà ju gbogbo àwọn yoku ni abúlé ṣùgbọ́n kò to, ó bẹ̀rẹ̀ si ra oko si titi dé oko àwọn ọmọ bàbá rẹ yoku. Eyi jẹ́ ki ó sọ àwọn ọmọ bàbá rẹ yoku di alágbàṣe ni oko ti wọn jogún. Inú àwọn ọmọ bàbá rẹ wọnyi kò dùn si wi pé wọn ti di atọrọjẹ àti alágbàṣe fún àbúrò wọn ninú ilé ara wọn.


Yorùbá ni “Àṣejù Baba Àṣetẹ́”. Ìgbéraga bẹ̀rẹ̀ si ṣe àṣejù, kò dúró lati má a fi ọrọ̀ rẹ yangà si gbogbo ará ilú pàtàki si àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ, ó jọ ara rẹ lójú, ó si nsọ ọ̀rọ̀ lai ronú tàbi gba ikilọ̀ àwọn àgbà ti wọn mọ ìbẹ̀rẹ̀ rẹ. Kò mọ̀ wi pé ohun ngbẹ́ ikòtò ìṣubú fún ara rẹ́. Ni ọjọ́ kan, ó pe ọ̀kan ninú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ti ó sọ di alágbàṣe ninú oko rẹ tẹ́lẹ̀ ó si bu, ó pe e ni aláìní dé ojú rẹ. Ẹ̀gbọ́n ké pẹ̀lú omijé lójú pé “Bi ó bá jẹ ìwọ ni Ọlọrun, ma ṣe iwà burúkú yi lọ, ṣùgbọ́n bi ó bá jẹ́ enia bi ti òhun, wà á ká ohun ti o gbin yi”.


Alágbàṣe ni oko Kòkó ti wọn jogún – Working as Labourers in their inheritted Cocoa farm.


Ni àárọ̀ ọjọ́ kan, Ìgbéraga ji ṣùgbọ́n kò lè di de nitori ó ti yarọ. Wọ́n gbe kiri titi fún itọ́jú ṣùgbọ́n asán ló já si. Ìṣòro yi jẹ ki ó ta gbogbo ohun ini rẹ ti ó fi nyangàn titi o fi di atọrọjẹ.


Ẹ̀kọ́ ìtàn yi ni pe àṣejù ohunkóhun kò dára pàtàki ki enia gbójúlé ọrọ̀ ilé ayé bi ẹni pé àwọn ti ó kù kò mọ̀ ọ́ ṣe, nitori Yorùbá sọ wi pé “kìtà kìtà kò mọ́là, Ká ṣiṣẹ́ bi ẹrú kò da nkan, Ọlọrun ló ngbé ni ga”.


Bv Olori Orente

131 comments:

 1. Replies
  1. Beeni, oku opolo!
   Omo Edo lemi oh😂😄😅😘😘😘


   ... Jesus is my worth!

   Delete
  2. Oya, e y'ago lo na
   Emi Diroyaliti, aare gbogbo alejo bulogu Esidike ti de

   Olori Orente, skelebe, omo Yoruba atata, itan re yi dun, gbongbon kan si. Se iwo lo poo papo ni abi o jii gbe?

   *ojoko o k'ese l'eri arawon pelu koboko olojumeje lowo*

   *eni t'oba tafelefele t'obe bi oya labe komenti mi ajegba*

   Delete
  3. E kú isé.

   1. Àmó kò sí ohun tí ó n jé 'yanga' nínú èdèe Yoruba.(there's no word like yanga in Yoruba language)

   2a. Ohun (fún ohun tí kò l'émìí) (for non living things)

   2b. Òun (him/herself) (fún ohun abèmí)
   👏👏👏👏

   Delete
  4. My Yoruba sucks. Make I waka pass

   Delete
 2. E ka ro
  Eku jor meta?
  So wa ok?
  Ma pada lola so gbo?
  Later

  😁

  ReplyDelete
  Replies
  1. BLOGLORD the real MVBM.

   Ba wo ni?
   Shey da da ni?

   Delete
  2. Bloglord
   Iya toh jaiye juu
   Emape ke to de oooo

   Delete
 3. Oya gbogbo omo kaaro ojire ebo sibi ooo
  Eja ka fomijomi toro oro

  ReplyDelete
  Replies
  1. Eshe gan Olori Orente 🙌🙌

   Delete
  2. Bv orente ese gan.eku iroyin

   Delete
  3. Adeola oshey gan
   Mogbadun itan yi

   Delete
 4. O seun jare Bv Orente,igberaga lo ma saju ibarun. Itan ti o mu ogbon wa ni ooo.

  Eyin temi bawo ni ooo???

  ReplyDelete
  Replies
  1. A wa, eleleleleelele a wa oh 😂😄😅😘🎵💃💃💃👏👏🎶🎵


   ... Jesus is my worth!

   Delete
 5. Yes oo.. I heat Yoruba


  Aah aah aah... Ma mA Ma MA fueh ni igbati

  Aah aah aah aah.... Shay owa alright


  Aah aah aah aah... Wa DOBO


  Abi, no be so Dem dey open mouth talk? Aah aah aah aah
  @ANONYMOUS ORUBEBE

  ReplyDelete
  Replies
  1. You heat yoruba? Oniranu oshi, u for cold yoruba.wo bo se ri bi igi ishana

   Delete
  2. Anonymous orubebe
   Olorun nikan lo ma saanu eee

   Delete
  3. @ Galore: Ori e ti gbaleee

   Delete
  4. @Saved.. Ka da fueh


   Unam ikot ,OLOBO 10kobo   Your head no tell you say Na "Hear" Abi wan write, no be "heat "   OLOBO townKaSU @Saved

   @ANONYMOUS ORUBEBE

   Delete
  5. Oloribuku orubebe oshi, omo ale jati jati, abiipabe

   Delete
  6. Hahaha... @Orente... Mabinu si mi.... Hear mo Feh kor


   @Gagaga... Oniranu, OLOBO townKaSU
   @ANONYMOUS ORUBEBE

   Delete
  7. Galore Enu e o da rara,lolz

   Delete
  8. @Galore: A fi olobo tankansu naa. Oloko tankansu nii mi.Were alasho.

   Delete
  9. Ikwakwakwakwakwakwakwakwakwakwa
   Moku ooo

   Koboko elenu meje mi da?
   Awon omo kan n ja n'ibi

   Delete
 6. Hmmm...oro baba oro. Ese Olukotan, igberaga ni n siwaju iparun. Eje ka saiye jeje ka ma ba parun lojiji.

  ReplyDelete
 7. Iya Oshoronga of Blogosphere AKA Mrs Always RIGHT25 October 2017 at 12:16

  Igberaga l'on shiwaju iparun. Good story. Never use your blessings to torment other people because the table can turn at any time. Olori orente eshe pupo o.

  ReplyDelete
  Replies
  1. Iya, hope you will now rest and enjoy your own local language!

   Delete
  2. Ekaabo ma
   Eje kama so ede waa

   Delete
  3. You are happy now 😂😂😂

   Delete
  4. Iya Oshoronga of Blogosphere AKA Mrs Always RIGHT25 October 2017 at 13:19

   @sexy daddy. Yes ooooo. At last.

   Delete
  5. Iya oh! Owo meji fun eyan kan!😘😘😘💃💃💃👏👏👏. Iya arogba aso ma ba le!


   ... Jesus is my worth!

   Delete
 8. Yoruba ti de oooo. ekaro gbogbo ni ile ooo.

  Mombo

  ReplyDelete
 9. Ehen good! Atleast, It will make Iya to leave our Igbo post in peace.
  *strolls out*

  ReplyDelete
  Replies
  1. Lol
   Eshe gan.

   Iya ewa ooo

   Mbo lo lo?

   Ewa se😂😂😂

   Delete
 10. Abeg my brain is paining me😁😂😂

  ReplyDelete
  Replies
  1. Lol
   Kilo de Sharon Aminu my future ex Bae?

   Delete
  2. Pele sweetheart mi,
   Its a lesson on pride falls befall a crash

   Delete
 11. Orente, Well done! Ah! Alaseju ni Igberaga o!

  ReplyDelete
 12. E ku agba Olori Orente. Eko gigidi ni eyi je fun gbogbo odo ode oni. Bi isu eni ba n ta amaa fowo booje ni. Shebi eni lari, shebi Eledua lomo la. Agba yin adale olori laafin.

  Awon omoge ati broda "instagram" e gbe joko ke wa kogbon.

  Oro ti jade, ashe ti tele lati enu Olori Orente!

  ReplyDelete
 13. Mi e gbo yourba. ..die die.... Ka aro o😙😙

  ReplyDelete
  Replies
  1. Ed na only this one you sabi speak?

   So ro joor!
   Ah!!! Ki ni gbo gbo eleyi 😂😂😂

   Delete
 14. Mi omo o-Me I don't know o!

  Tani- who is that?

  Oloshoo-ashi

  Oko-A village in my state.

  Obo ni e- You are a monkey!😂

  Bawo ni o my Yoruba friends!😃

  ReplyDelete
  Replies
  1. Nekwanu umunnem na aRAPuzi Yoruba.

   TGW
   Ijele dike
   I did not see you yesterday during Igbo post. Mbo lo lo?

   Delete
  2. LMAO @ Na arapuzi Yoruba🤣🤣🤣🤣🤣

   Chike Chyko!
   Nna ikalili okwu ikotelu!🙌

   Delete
 15. Lesson well learnt. Thank you BV orente.

  ReplyDelete
 16. As I be Yoruba girl sef I no fit read everything.....eku owuro ooo.

  Shey daadaa le wa?

  Olori orente you forgot to put copied cos I'm sure u no fit put those signs

  ReplyDelete
  Replies
  1. Lol abi
   Kasha ma so ede wa nu

   Delete
  2. Same boat,but I dey try for writing.

   Delete
 17. Omo Yoruba ni emi sugbon mio o mo yoruba ka dada... Eshe gan Olori..

  ReplyDelete
 18. Ki lo so?

  Mi o gbo...

  Kini gbo gbo eleyi? 😂😂😂😂

  Olori Orente eshe gan 🙌🙌🙌

  Omo Yoruba ewa wale ooo

  ReplyDelete
  Replies
  1. Pride is before a crash
   Itumo niyen

   Delete
  2. Pride goes before a fall!! Not crash..kmt!

   Delete
 19. Replies
  1. Oremi one Nigeria
   Modupe ipe onife ede wa

   Delete
 20. Igberaga ma n kò eyan si wahala ni
  BV olori orente this is a very good write up.

  LEP😛

  ReplyDelete
 21. Ehen I forgot, Olori Oshe kpukpo!👍

  ReplyDelete
  Replies
  1. Hahaha! TGW it's ose pupo, this one you write is Yoruba in Igbo language

   Delete
 22. O seun pupo alejo buloogu Orente (blog visitor orente)
  igberaga lo n siwaju iparun, agidi okan lo n siwaju isubu.

  Onirele lo le jogun aye, bi isu ba ti e ta, sebi o ye ka dowo bo je ni.

  Eleduwa paapaa korira agberaga sugbon o fi owo fun awon onirele.

  O seun pupo leekansi Arabinrin mi, tubo maa gbe Asa Yoruba ga nibikibi.

  Eyin ara mi lori buloogu alayo yi, Ire oooo

  Alejo Buloogu OmoBee. (BV OmoBee)

  ReplyDelete
  Replies
  1. Alejo omo bee
   Eshey gan,mofe ka ma GBE ede wa laruge

   Delete
  2. O trirai gaan OmoBee!😂😄😘😘😘👏👏


   ... Jesus is my worth!

   Delete
 23. Igberaga lon siwaju Iparun- Pride goes before a fall
  Aseju ohun gbogbo ko da- too much everything is bad,do everything in moderation.
  Agboju logun fira re fun iyaje- the one who relies on family wealth,only exposes his or herself to suffering.
  Olowo kan otosi mefa,otosi ni gbogbo won- A rich man in the midst of six poor men,translate to seven poor men,teach people how to make wealth rather than giving them piecemeal.

  Lessons of this write up.

  Aunty Stella ese gan ni o

  I will be waiting for another write up in Igbo,will be ready to interpret for you, ngwanu...

  ReplyDelete
 24. Iloron ikotun Yuri gbede fii ko Ryan igberaga.Bv Orente.Bawo in..Lol

  ReplyDelete
  Replies
  1. Ki ni eleyi bayii?

   Delete
  2. Iya Oshoronga of Blogosphere AKA Mrs Always RIGHT25 October 2017 at 14:59

   Welldone sexy daddy. You tried jare. Lol. Sugbon oloun nikan lo mo nkan ti e ko yi.

   Delete
  3. @ 13:56; Ko ye mi oh! 😂😄😅


   ... Jesu ni worth mi oh🤣😂😄😂😄

   Delete
  4. Ikwakwakwakwakwakwakwakwakwakwa

   Baba kekere, Ojuigo, ede wo leko yi?
   E fe fowaloju ni?

   Delete
 25. Eka'aro o

  Ekujo'meta

  She'wa'ok?

  BV Olori Eshe gan!!

  ReplyDelete
  Replies
  1. Ekabo momsi Kendrick
   Eshey gan

   Delete
  2. Chike am not oh African magic yoruba did it's magic oh.....lol. I missed d Igbo post yesterday.

   Delete
 26. Igberaga ni o siwaju iparun. Mase se igberaga si enikeni ki o ba le gbe ile aye pe

  ReplyDelete
 27. awon eyon mi bawo ni nkan be?

  mo fe lo yagbe se...
  mon bo oh.... *releases fart*

  ReplyDelete
  Replies
  1. Olori dimokokorkus
   Ema jeki inu ile yen Marun oooo
   Shey e understand story yen

   Delete
  2. You're a real clown 🤡....sdk rocks...

   Bv jatz

   Delete
  3. Sdk ma pa wa pelu isó atî igbè

   Delete
  4. Lmao!! Stella o gbadun rara

   Delete
  5. Stella o funny gan!

   E'pele o @ release fart

   Delete
  6. @ Stella, e Pele ma. Se iso yen ko dun yi ni idi? 😐(I hope d fart no pain u for bum. Na so we dey greet elders wey fart. Lola)

   Delete
 28. Iya Oshoronga of Blogosphere AKA Mrs Always RIGHT25 October 2017 at 13:17

  Lol @ mo fe lo yagbe se
  @ bawo ni nkan be. Omg lwkmd

  ReplyDelete
 29. Stella you no well i tell you! Stella ala je shu!

  ReplyDelete
 30. Iya Oshoronga of Blogosphere AKA Mrs Always RIGHT25 October 2017 at 13:34

  At least mo ti ri pe kosi conspiracy lati le awa yoruba kuro nibiyi. Bo ti e je pe once in a blue moon la ma ri iru post bayi. Eshe o.

  ReplyDelete
  Replies
  1. Amama shey ni gbogbo igba
   Tie EBA ni suggestions ,ki a Jo so

   Delete
  2. Laye kó si nkó to má jobè
   Won tî bi wan da

   Olori orente Ku isè o

   Delete
  3. I think I know what 'lati' means.lol
   My interpreter isn't close by todayyy ooohhhh🙆🏽‍♂️
   Lobatan!!!

   Delete
 31. Bikonu ogini by this? My eyes are paining me abeg. Can't even pronounce one word sef...... Odikwa risky ooo. Am out

  ReplyDelete
 32. Aa da fun yin o Olori Orente. Gbo gbo ton pka yin lekun, Olorun Oba afi pka yin lerin ayo.

  ReplyDelete
 33. Nice one. Head wan knack cos I read am back to back. It's worth it though. Keep it up Orente

  ReplyDelete
  Replies
  1. Hahahaha... I no even read am... I don't know how to read it... But I love it   I be barracks person, so I picked few Nigerian languages
   @ANONYMOUS ORUBEBE

   Delete
 34. Ni bo!....Oyaaaaaaa!!!!!
  Shey alafia le wa eyin befeeee's(bv's)lolzzzz

  ReplyDelete
 35. Yoruba ni ede ti olorun yi o fi se idajo aye, iwo ti ko ba gbo ti e ba e lojo idajo niyen o, ki olorun ma ni ki owo paradise ki o lo ro pe ina lo pe. Olori orente o ti ri orun wo. Ori e wa nibe

  ReplyDelete
 36. Mom binu gan. Awon mi ko ki mi pe STELLA Eku igbe

  ReplyDelete
  Replies
  1. Lol Stella eku igbe yi ya oooo,idi a tura ooo

   Delete
  2. Hahhhahhaha chai u no go kill person. Katu ki e lori egbe?tor mo no.....

   Delete
  3. Eku igbe kor,eku ito ni,onimu reluwe.

   Delete
  4. Eku igbe kor eku ito ni,onimu reluwe.

   Delete
 37. BV Orente, E seun gan o. Mo gbadun itan yii gan ni.

  ReplyDelete
 38. Bv Olori Orente, eku laakaye mode gbadun Itan yi gan ni

  ReplyDelete
 39. Stella o se gidi gaa

  ReplyDelete
 40. Olori orente ose gaaani o.

  ReplyDelete

 41. Eku ise opolo, eyin omo kaaro ojiire.

  Igberaga ko dara, aseju ni baba asete

  ReplyDelete
 42. Eseun Olori o..agba o ni tan lorile o. Lotito,igberaga lo n siwaju iparun. Eni ti aye ba nye loni ko rora,obiri ni aye,to baa fi siwaju atu fiseyin. Iwa lewa omo eniyan.

  ReplyDelete
  Replies
  1. Esheun gan
   Eje kama GBE ede wa laruge

   Delete
 43. Eyin eyan mi, se dada lewa. Mo n gbadun yin losan yi. WaSe oriire olori orente. Bo tie jepe mo pe de die. Olorun a saanu wa laye buhari yi oo.i don Taya abeg

  ReplyDelete
  Replies
  1. E tii peju
   Ekabo sori eto
   Olorun ama yo wa oooo

   Delete
 44. Wawuuuu!!!!! Olori Orente, in as much as i don't like you i doff my hat for this write up. E sa ku ise opolo. opolo yin o ni jona oo. Iwa pele lodara julo.igberaga man gbeni sanle ni.

  ReplyDelete
  Replies
  1. Haaa mama ke kini mo shey oo
   Mi kin ja oooo,jeje lomo eko nlo
   Timba to seyin so eyin ejor emabinu faaa
   Eshey gan
   Irepolodun ooo

   Delete
 45. Emi koni mo ko Itan yen oooo
  Mokoro wipe ako gbodo je ki ede wa Ku lailai
  Mojuba eni to ko
  Mode dupe lowo olori korkus toh bawa GBE sita

  Ema jeki ede wa Ku
  Eni ti oba ni nkan mi ta ma jiroro ka GBE wa sori tabili
  Inu mi dun gan wipe gbogbo awa omo oduduwa LA fowosopo
  Olorun ada wa sii ooo
  Inu wa yio dun kaale
  Eje ka GBE EDE ati ASA wa laruge
  Eshey gan ni ooo
  Ire ooooooo.

  ReplyDelete

Disclaimer: Comments And Opinions On Any Part Of This Website Are Opinions Of The Blog Commenters Or Anonymous Persons And They Do Not Represent The Opinion Of StellaDimokoKorkus.com

Pictures and culled stories posted on this site are given credit and if a story is yours but credited to the wrong source,Please contact Stelladimokokorkus.com and corrections will be made..

If you have a complaint or a story,Please Contact StellaDimokoKorkus.com Via

Sdimokokorkus@gmail.com
Mobile Phone +4915210329280