Stella Dimoko Korkus.com: Oriki ilu Eko

Advertisement

Advertisement - Mobile In-Article

Thursday, August 16, 2018

Oriki ilu Eko

Eku ise oh...Emi ni Stella......Olori ti de noni mofe se intro noni,toripe Olori ko mo se.......Anytime te ba read intro ,emi lo se.
Ejor e ma wo me side eyes,me ron e ise! *tongue click noni*



Leeni, oriki ilu Eko Lamuwa....aki gbogbo omo eko towa Nile oo, Eko onibaje .....


Eko Akete Ile Ogbon
Eko Aromi sa legbe legbe
Eko aro sese maja
Eko akete ilu okun alagbalugbu omi,
Ta lo ni elomi l'eko? ebiwon pe talo ni abatabutu baba omikomi, talo laabata buutu baba odo kodo
Eko adele ti angere nsare ju eniyan elese meji lo
Eni to o ba lo si ilu eko tiko ba gbon, Koda, bo lo si ilu oyinbo ko legbon mo
Afefe toni pon wa ni bebe okun ti yin, faaji to ni pan wa ni bebe osa
Eko omo osha nio ose, mase kutere, osha n gbobi, kutere n gbori
Eyin lomo afinju woja marin gbendeke, obun woja n wapa sio sio


Eyo o Aye'le Eyo o, Eyo baba n teyin to n fi golu n sere, eyin oni sanwo onibode, odilee


Eje ka jiroro ohun meremere toti tilu eko jade????


Olori Orente



This about the Eulogy of Lagos State

23 comments:

  1. αΊΈkọ ọ ni bajαΊΉ ọ nitori Olọrun.πŸ˜€πŸ˜€πŸ˜€πŸ˜€πŸ˜€πŸ˜€

    ReplyDelete
    Replies
    1. O baje ti πŸ˜‚πŸ˜‚πŸ˜‚πŸ˜‚

      Delete
  2. Eko bake tiiiii

    Stella, intro re yi lagbara o!πŸ˜€

    Omo iya mi, boo ni?

    ReplyDelete
    Replies
    1. Stella o fe gba rara
      Omo iya, mowapa
      Oko yin Loni eni ohπŸ˜‚πŸ˜‚

      Delete
    2. Eko baje tiii

      Autocorrect fi le be! Ko wa be!

      Delete
    3. ko kuku ko mi lenu, autocorrect lo n'se ti e ni jare. hehehehehe

      Delete
  3. Bawoni o, se nlo. Adupe Jesu o

    ReplyDelete
  4. Eleyi dara ooo,a mu wa mo ori ilu wa ni oniranran,mafi arabale di ijo ti oma kan ilu mi

    ReplyDelete
  5. Enle nibe yen oh Iyaafin Orente, ibeere ni emi fe bere oh... Ehen, nje awon eya wo gangan lote ilu eko do? ati gbo ninu itan wipe awon eya biini ni, bee sini atunti gbo wipe awon eya eegun abi awori niwon te eko do. Awon kan te so wipe awon oyinbo Portugi abi Brasili ni paapaa. Ejowo Olori, ewo gan ni otito oro nibe oh?

    ReplyDelete
    Replies
    1. Bi emi shey gbo, awon awori ni won nilu eko
      Awon oyinbo komu olaju ati esin wani

      Ti aba ni eni to mo nko mi yato si iyi ta soyi
      Ejeka keko

      Delete
  6. Enle nibe yen oh Iyaafin Orente, ibeere ni emi fe bere oh... Ehen, nje awon eya wo gangan lote ilu eko do? ati gbo ninu itan wipe awon eya biini ni, bee sini atunti gbo wipe awon eya eegun abi awori niwon te eko do. Awon kan te so wipe awon oyinbo Portugi abi Brasili ni paapaa. Ejowo Olori, ewo gan otito oro nibe oh?

    ReplyDelete
    Replies
    1. ibeere yi lagbara o, olori orente ni lati lo se risachi lati mo idahun re. (mo rerin muse)

      Delete
    2. Scarlet Gruber... .mo rerin
      Moti gbiyanju πŸ‘†. ...emi na fe keko

      Delete
  7. Stella fe fun mi ni ori fifo pelu intro yii. Kilode!!!
    Olori orente, awon gbewiri ko ni gbe gege ikowe yin lo o. Aase.

    ReplyDelete
  8. E seun gan Olori fun idahun yin, sugbon loju temi oh o dabi enipe kosi eya kankan to ni eko. Eyi jasi wipe gbogbo wa lani eko. Emi tiri hausa ati ibo to n ta ile ni eko oh, omo Togo ati Bene si ngba owo omo onile leko. Nipa idi eyi, eko ki nse tenikan.... Gbogbo wa lani Eko oooh.

    ReplyDelete
    Replies
    1. Omo iyami, mogba πŸ‘πŸ‘πŸ‘πŸ‘
      Gbogbo wa la leko
      Eko oni baje

      Delete
  9. Eko ko gba gbere, Eko o gba gbere rara ooooo

    ReplyDelete
    Replies
    1. 🎡🎡🎡🎡🎡

      Delete

Disclaimer: Comments And Opinions On Any Part Of This Website Are Opinions Of The Blog Commenters Or Anonymous Persons And They Do Not Represent The Opinion Of StellaDimokoKorkus.com

Pictures and culled stories posted on this site are given credit and if a story is yours but credited to the wrong source,Please contact Stelladimokokorkus.com and corrections will be made..

If you have a complaint or a story,Please Contact StellaDimokoKorkus.com Via

Sdimokokorkus@gmail.com
Mobile Phone +4915210724141